Native Bible

Psalms 31:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.

Psalms 31:19 in English

Psalms 31:19 · Berean Standard Bible

How great is Your goodness which You have laid up for those who fear You, which You have bestowed before the sons of men on those who take refuge in You!

Context

17Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú. 18Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn, wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo. 19Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn. 20Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n. 21Olùbùkún ni Olúwa, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.