Native Bible

Psalms 16:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

Psalms 16:3 in English

Psalms 16:3 · Berean Standard Bible

As for the saints in the land, they are the excellence in whom all my delight resides.

Context

1Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà. 2Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi, lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.” 3Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà. 4Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn. Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi. 5Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.