Native Bible

Psalms 142:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi èmi kò ní ààbò; kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

Psalms 142:4 in English

Psalms 142:4 · Berean Standard Bible

Look to my right and see; no one attends to me. There is no refuge for me; no one cares for my soul.

Context

2Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀. 3Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀. 4Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi èmi kò ní ààbò; kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi. 5Èmi kígbe sí ọ, Olúwa: èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.” 6Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.