Saamu 140:9
Psalms 140:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni, jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Psalms 140:9 in English
Psalms 140:9 · Berean Standard Bible
May the heads of those who surround me be covered in the trouble their lips have caused.
Context
7Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà. 8Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela. 9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀. 10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára,
Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́. 11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.