Native Bible

Psalms 140:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára, Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jíjìn, kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.

Psalms 140:10 in English

Psalms 140:10 · Berean Standard Bible

May burning coals fall on them; may they be thrown into the fire, into the miry pits, never to rise again.

Context

8Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela. 9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni, jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀. 10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára, Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jíjìn, kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́. 11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé; ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú. 12Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.