Saamu 133
Psalms 133 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀. 2Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀. 3Bí ìrì Hermoni
tí o sàn sórí òkè Sioni.
Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,
àní ìyè láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.