Native Bible

Psalms 122 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Listen to Saamu 122
1Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.” 2Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ, ìwọ Jerusalẹmu. 3Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan. 4Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà Olúwa, ẹ̀rí fún Israẹli, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa. 5Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi. 6Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere. 7Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀. 8Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsin yìí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀. 9Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.