Native Bible

Psalms 106:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

Psalms 106:39 in English

Psalms 106:39 · Berean Standard Bible

They defiled themselves by their actions and prostituted themselves by their deeds.

Context

37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà. 38Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀. 39Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn. 40Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀ 41Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.