Native Bible

Psalms 106:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

Psalms 106:37 in English

Psalms 106:37 · Berean Standard Bible

They sacrificed their sons and their daughters to demons.

Context

35Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn. 36Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn. 37Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà. 38Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀. 39Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.