Saamu 102:4
Psalms 102:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
Psalms 102:4 in English
Psalms 102:4 · Berean Standard Bible
My heart is afflicted, and withered like grass; I even forget to eat my bread.
Context
2Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá. 3Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
egungun mi sì jóná bí ààrò. 4Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi. 5Nítorí ohùn ìkérora mi,
egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi. 6Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.