Saamu 10:12
Psalms 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
Psalms 10:12 in English
Psalms 10:12 · Berean Standard Bible
Arise, O LORD! Lift up Your hand, O God! Do not forget the helpless.
Context
10Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀. 11Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.” 12Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú. 13Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
“Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”? 14Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.