Native Bible

Psalms 10:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

Psalms 10:14 in English

Psalms 10:14 · Berean Standard Bible

But You have regarded trouble and grief; You see to repay it by Your hand. The victim entrusts himself to You; You are the helper of the fatherless.

Context

12Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú. 13Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run? Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀, “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”? 14Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba. 15Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi; pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀ tí a kò le è rí. 16Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé; àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.