Òwe 6:24
Proverbs 6:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.
Proverbs 6:24 in English
Proverbs 6:24 · Berean Standard Bible
to keep you from the evil woman, from the smooth tongue of the adulteress.*
Context
22Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;
nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;
nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. 23Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,
ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,
àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí
ni ọ̀nà sí ìyè. 24Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,
kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì. 25Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ
tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra. 26Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,
ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.