Native Bible

Proverbs 6:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè.

Proverbs 6:23 in English

Proverbs 6:23 · Berean Standard Bible

For this commandment is a lamp, this teaching is a light, and the reproofs of discipline are the way to life,

Context

21Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. 22Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. 23Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè. 24Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì. 25Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.