Òwe 30:13
Proverbs 30:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
Proverbs 30:13 in English
Proverbs 30:13 · Berean Standard Bible
There is a generation—how haughty are their eyes and pretentious are their glances—
Context
11“Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn
tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn. 12Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn
síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn; 13àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,
tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga. 14Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà
àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ
láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé
àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn. 15“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì.
‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké.
“Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,
mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.