Native Bible

Proverbs 30:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’:

Proverbs 30:15 in English

Proverbs 30:15 · Berean Standard Bible

The leech has two daughters: Give and Give. There are three things that are never satisfied, four that never say, ‘Enough!’:

Context

13àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga. 14Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn tálákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn. 15“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì. ‘Mú wá! Mú wá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó!’: 16Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀ tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’ 17“Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọ́ràn sí ìyá, ẹyẹ ìwò ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.