Òwe 30:10
Proverbs 30:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi.
Proverbs 30:10 in English
Proverbs 30:10 · Berean Standard Bible
Do not slander a servant to his master, or he will curse you, and you will bear the guilt.
Context
8Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;
má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,
ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan. 9Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ
kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’
Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè
kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi. 10“Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,
kí ó má ba fi ọ́ bú, kí ìwọ má ba jẹ̀bi. 11“Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn
tí wọn kò sì súre fún àwọn ìyá wọn. 12Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn
síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.