Òwe 28:8
Proverbs 28:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
Proverbs 28:8 in English
Proverbs 28:8 · Berean Standard Bible
He who increases his wealth by interest and usury lays it up for one who is kind to the poor.
Context
6Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù
ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla. 7Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀. 8Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù
ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà. 9Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,
kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra. 10Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú
yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀
ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.