Native Bible

Proverbs 28:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀.

Proverbs 28:7 in English

Proverbs 28:7 · Berean Standard Bible

A discerning son keeps the law, but a companion of gluttons disgraces his father.

Context

5Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára. 6Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla. 7Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀. 8Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà. 9Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.