Native Bible

Proverbs 27:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

Proverbs 27:12 in English

Proverbs 27:12 · Berean Standard Bible

The prudent see danger and take cover; but the simple keep going and pay the penalty.

Context

10Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdààmú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà sí ni. 11Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi. 12Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀. 13Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe. 14Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.