Native Bible

Proverbs 27:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe.

Proverbs 27:13 in English

Proverbs 27:13 · Berean Standard Bible

Take the garment of him who posts security for a stranger; get collateral if it is for a foreigner.*

Context

11Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi. 12Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀. 13Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjèjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oníṣekúṣe. 14Bí ènìyàn kan ń kígbe súre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè. 15Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.