Òwe 26:25
Proverbs 26:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
Proverbs 26:25 in English
Proverbs 26:25 · Berean Standard Bible
When he speaks graciously, do not believe him, for seven abominations fill his heart.
Context
23Ètè jíjóni, àti àyà búburú,
dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò. 24Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀
ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà. 25Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́
nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀. 26Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn
ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba. 27Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.
Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.