Native Bible

Proverbs 26:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

Proverbs 26:24 in English

Proverbs 26:24 · Berean Standard Bible

A hateful man disguises himself with his speech, but he lays up deceit in his heart.

Context

22Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ. 23Ètè jíjóni, àti àyà búburú, dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò. 24Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà. 25Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀. 26Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.