Òwe 24:11
Proverbs 24:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
Proverbs 24:11 in English
Proverbs 24:11 · Berean Standard Bible
Rescue those being led away to death, and restrain those stumbling toward the slaughter.
Context
9Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn. 10Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó! 11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà. 12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe? 13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.