Òwe 24:13
Proverbs 24:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
Proverbs 24:13 in English
Proverbs 24:13 · Berean Standard Bible
Eat honey, my son, for it is good, and the honeycomb is sweet to your taste.
Context
11Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà. 12Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe? 13Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu. 14Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ
ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo. 15Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
láti gba ibùjókòó olódodo,
má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.