Native Bible

Proverbs 20:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.

Proverbs 20:4 in English

Proverbs 20:4 · Berean Standard Bible

The slacker does not plow in season; at harvest time he looks, but nothing is there.

Context

2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. 3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà. 4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan. 5Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde. 6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.