Native Bible

Proverbs 20:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

Proverbs 20:3 in English

Proverbs 20:3 · Berean Standard Bible

It is honorable for a man to resolve a dispute, but any fool will quarrel.

Context

1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n. 2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. 3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà. 4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan. 5Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.