Native Bible

Proverbs 19:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.

Proverbs 19:9 in English

Proverbs 19:9 · Berean Standard Bible

A false witness will not go unpunished, and one who pours out lies will perish.

Context

7Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì, mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ le rí wọn rárá. 8Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú. 9Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun. 10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé. 11Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.