Òwe 19:8
Proverbs 19:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
Proverbs 19:8 in English
Proverbs 19:8 · Berean Standard Bible
He who acquires wisdom loves himself; one who safeguards understanding will find success.
Context
6Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́. 7Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,
mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
kò tilẹ̀ le rí wọn rárá. 8Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;
ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú. 9Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà
ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun. 10Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.