Òwe 19:22
Proverbs 19:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
Proverbs 19:22 in English
Proverbs 19:22 · Berean Standard Bible
The desire of a man is loving devotion; better to be poor than a liar.
Context
20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,
ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n. 21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí. 22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;
ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ. 23Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ìyè wá;
nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu. 24Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ;
kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.