Òwe 19:20
Proverbs 19:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
Proverbs 19:20 in English
Proverbs 19:20 · Berean Standard Bible
Listen to counsel and accept discipline, that you may be wise the rest of your days.
Context
18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀. 19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀;
bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. 20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,
ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n. 21Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí. 22Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀;
ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.