Native Bible

Proverbs 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀.

Proverbs 19:18 in English

Proverbs 19:18 · Berean Standard Bible

Discipline your son, for in that there is hope; do not be party to his death.

Context

16Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú. 17Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá, yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe. 18Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀. 19Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀; bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. 20Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.