Òwe 14:8
Proverbs 14:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
Proverbs 14:8 in English
Proverbs 14:8 · Berean Standard Bible
The wisdom of the prudent is to discern his way, but the folly of fools deceives them.
Context
6Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye. 7Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀. 8Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ. 9Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere. 10Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀
kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.