Òwe 12:25
Proverbs 12:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
Proverbs 12:25 in English
Proverbs 12:25 · Berean Standard Bible
Anxiety weighs down the heart of a man, but a good word cheers it up.
Context
23Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. 24Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba
ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. 25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. 26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà. 27Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ
ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.