Native Bible

Proverbs 12:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.

Proverbs 12:24 in English

Proverbs 12:24 · Berean Standard Bible

The hand of the diligent will rule, but laziness ends in forced labor.

Context

22Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. 23Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. 24Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. 25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. 26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.