Native Bible

Proverbs 12:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.

Proverbs 12:27 in English

Proverbs 12:27 · Berean Standard Bible

A lazy man does not roast his game, but a diligent man prizes his possession.

Context

25Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. 26Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà. 27Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀. 28Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.