Native Bible

Proverbs 11:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.

Proverbs 11:9 in English

Proverbs 11:9 · Berean Standard Bible

With his mouth the ungodly man destroys his neighbor, but through knowledge the righteous are rescued.

Context

7Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun; gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. 8A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú. 9Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà. 10Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀; nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan. 11Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.