Òwe 11:7
Proverbs 11:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun; gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.
Proverbs 11:7 in English
Proverbs 11:7 · Berean Standard Bible
When the wicked man dies, his hope perishes, and the hope of his strength vanishes.
Context
5Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn,
ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀. 6Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là,
ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́. 7Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun;
gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. 8A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀,
ibi wá sórí ènìyàn búburú. 9Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,
ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.