Òwe 11:16
Proverbs 11:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
Proverbs 11:16 in English
Proverbs 11:16 · Berean Standard Bible
A gracious woman attains honor, but ruthless men gain only wealth.
Context
14Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú
ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú. 15Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu. 16Obìnrin oníwà rere gba ìyìn
ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan. 17Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore
ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀. 18Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ
ṣùgbọ́n ẹni tó fúnrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.