Òwe 10:12
Proverbs 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
Proverbs 10:12 in English
Proverbs 10:12 · Berean Standard Bible
Hatred stirs up dissension, but love covers all transgressions.*
Context
10Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn,
aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun. 11Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,
ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú. 12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀. 13Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,
ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye. 14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,
ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.