Òwe 10:13
Proverbs 10:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye, ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
Proverbs 10:13 in English
Proverbs 10:13 · Berean Standard Bible
Wisdom is found on the lips of the discerning, but a rod is for the back of him who lacks judgment.
Context
11Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,
ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú. 12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀. 13Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye,
ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye. 14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,
ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun. 15Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.