Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni, wọn yóò sì jẹ́ mímọ́, àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.

Obadiah 1:17 in English

Obadiah 1:17 · Berean Standard Bible

But on Mount Zion there will be deliverance, and it will be holy, and the house of Jacob will reclaim their possession.

Context

15“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ. 16Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí; wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùn wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí. 17Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni, wọn yóò sì jẹ́ mímọ́, àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn. 18Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.” Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀. 19Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.