Obadiah 1:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
Obadiah 1:15 in English
Obadiah 1:15 · Berean Standard Bible
For the Day of the LORD is near for all the nations. As you have done, it will be done to you; your recompense will return upon your own head.
Context
13Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,
ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀
nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,
ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. 14Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà
láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.
Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú
wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn. 15“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé
lórí gbogbo àwọn kèfèrí.
Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;
ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ. 16Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi,
bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí;
wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùn
wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí. 17Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni,
wọn yóò sì jẹ́ mímọ́,
àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.