Native Bible

Numbers 4:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

Numbers 4:39 in English

Numbers 4:39 · Berean Standard Bible

everyone from thirty to fifty years old who came to serve in the work at the Tent of Meeting.

Context

37Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 38Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn. 39Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 40Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n (2,630). 41Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.