Native Bible

Numbers 26:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

Numbers 26:11 in English

Numbers 26:11 · Berean Standard Bible

However, the line of Korah did not die out.

Context

9àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà. 10Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀. 11Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú. 12Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini; 13ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.