Numeri 23:8
Numbers 23:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú? Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí Olúwa kò bá wí?
Numbers 23:8 in English
Numbers 23:8 · Berean Standard Bible
How can I curse what God has not cursed? How can I denounce what the LORD has not denounced?
Context
6Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. 7Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé,
“Balaki mú mi láti Aramu wá,
ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá
Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi;
wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’ 8Báwo ní èmi ó ṣe fi bú
àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?
Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí
àwọn tí Olúwa kò bá wí? 9Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,
láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.
Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀
wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè. 10Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu
tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli?
Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo,
kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.