Numeri 23:6
Numbers 23:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu.
Numbers 23:6 in English
Numbers 23:6 · Berean Standard Bible
So he returned to Balak, who was standing there beside his burnt offering, with all the princes of Moab.
Context
4Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.” 5Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.” 6Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. 7Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé,
“Balaki mú mi láti Aramu wá,
ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá
Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi;
wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’ 8Báwo ní èmi ó ṣe fi bú
àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?
Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí
àwọn tí Olúwa kò bá wí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.