Numeri 23:19
Numbers 23:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
Numbers 23:19 in English
Numbers 23:19 · Berean Standard Bible
God is not a man, that He should lie, or a son of man, that He should change His mind. Does He speak and not act? Does He promise and not fulfill?
Context
17Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?” 18Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ,
“Dìde, Balaki;
kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori. 19Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.
Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?
Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ? 20Èmi gba àṣẹ láti bùkún;
Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà. 21“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu,
kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli.
Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.
Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.