Numeri 23:17
Numbers 23:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”
Numbers 23:17 in English
Numbers 23:17 · Berean Standard Bible
So he returned to Balak, who was standing there by his burnt offering with the princes of Moab. “What did the LORD say?” Balak asked.
Context
15Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.” 16Olúwa pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.” 17Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?” 18Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ,
“Dìde, Balaki;
kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori. 19Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.
Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?
Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.