Numeri 11:32
Numbers 11:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí, ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.
Numbers 11:32 in English
Numbers 11:32 · Berean Standard Bible
All that day and night, and all the next day, the people stayed up gathering the quail. No one gathered less than ten homers,* and they spread them out all around the camp.
Context
30Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́. 31Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká. 32Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí, ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó. 33Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrín eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn. 34Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kibirotu-Hattaafa nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúwà oúnjẹ sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.